Thursday, 23 March 2017

Itan igbesi aye e Bonetta, Sarah Forbes (1843-1880

Bonetta, Sarah Forbes (1843-1880)

Arabirin Sarah Forbes Bonetta,  je omo Oba egbado yewa ni Ipinle Ogun. Won bi Bonetta ni odun 1843, sugbon ako mo oruko awon ti won bi I sugbon itan filele wipe omo oba egbado ni oje. Awon obi ati awon omo iya ati baba re ti ku, nipase awon ako ni leru ni odun 1847
Gezo ti oje oba ilu dahomey ko ogun ja oke odan, ni abule ti won bi Sarah si, Oba Gezo je onijagidijagan, ti ki igbo kigba eniyan ti oferan owo eru sise lopolopo ti kosi se tan lati dawo re duro, leyin ti Oba birin ti ilu England ti pase pe ki gbogbo igberiko dawo owo eru sise duro, ni akoko yi ni won ko gbogbo idile Sarah leru ti won si pa awon obi re ati awon egbon re sugbon fun idi kan tabi ekeji won da sarah si titi di odun 1849.  Ni odun 1849 yi ni Ogbeni Fredick Forbes se abewo si ilu Dahomey lati parowa fun Oba Gezo wipe ki odawo owo eru sisi duro.  Ni akoko yi ni Fredrick se akiyesi omode birin yi ti osi be Oba Gezo wipe ki o fi omobirin naa sile fun ohun ki ohun mu lo fise ebun fun Oba birin Victoria. O parowa fun wipe omobirin naa aje ebun lati owo oba ile adulawo si oba ilu oyinbo. Inu oba Gezo dun lati gbo alaye ti Fredrick se, osi fa omo birin naa fun Fredrick. Omobirin na gbe pelu Fredrick fun bi Odun mefa ni ile alawo dudu, ose Iribomi, osi yi oruko pada kuro ni Aina si Sarah Forbes Bonneta. Fredrick se alaye wi pe omo naa jafafa, osi ni ebun orin kiko, osi gbo ede geesi beeni osi le so. Ogbon ori e ju ti awon omo alawo funfun miran ti won jijo je egbe lo. Osi ni afojusi ati eran iferan lara. 
  
Fredrick mu Sarah losi ilu Londonu ni odun 1850 lati lori oba birin Elisabeti. Inu Elisabeti dun lati ri omo naa, wipe oje omo ti ojafafa. Ni igba ti Fredrick ku ni odun 1851 Oba birin Elisabeth gba a sodo gege bi omo osin se itoju re. leyin odun kan ti sarah de ilo Londunu ni obere si se aisan iko, idi niyi ti won mu lo si ilu freetown ni Sierra Leone, ibe ni oti ka iwe ti osi yege ti osi pada si ilu londonu ni odun 1855. Ni osu kinni odun 1862 ni igba ti ope omo odun mokandinlogun ni opade onisowo Yoruba Captain Jame Pinso Labulo ti oje omo ogbon odun ti won si se igbeyawo ninu osu kejo odun naa. Awon mejeji gbe ni ilu londonu fun igba di e ki won to pada si ilu sierra Leonne. Obi omo obirin ti oso orukore ni Victoria pelu Ase lati owo Oba birin Victoria ni ilu London, leyin eyi ni otun bi okunrin meji. Sara jade laye ni odun 1867 ni pase iko o fere, won se ayeye igbehin ti olarinrin fun, Oba birin Victoria si mu awon omo re gege bi omo ti osi nse toju won.  Awon iran Sarah wa ni agbegbe ilu eko ni ode oni ti won gbe ni irorun.

Tuesday, 21 March 2017

Awon osere pataki bii Tuface,  Darey,  Adekunle Gold,  fakoyo ni bi concert ti Olori Wuraola Adeyeye fi lole fun awon omo alaini.

Awon osere pataki bii Tuface,  Darey,  Adekunle Gold,  fakoyo ni bi concert ti Olori Wuraola Adeyeye fi lole fun awon omo alaini.

Concert ti akori re je "fifi funni pada" eyi ti otumo siwipe ti olorun ba fun,  iwo naa fi fun awon alaini pada.

Lotito ni wipe concert yi ti waye osi ti lo,  sugbon ipa ti concert yi ko ni inu aye awon omo alaini ko le di ohun igbagbe laye laye.

Idi ni wipe,  Olori wuraola pelu awon eniyay jankan jankan lawujo ni won se agbateru ayeye naa. Awon elere ori itage,  akorin,  awon oloye ati olola lawujo ni o pejo sibe lati fi ohun mere mere da awon omo alaini lola. Ninu awon lamilaaka to peju si ibi eto orin, ati ijo ni ojo naa ni

Tuface Idibia, Darey Art Alade, Adekunle Gold, Waje, Cobhams, Sound Sultan, Kenny Blaq, Funbi,  Lamboghini ati bebe loo.

Lara awon oloye ati oloselu to pejo sibi ayeye naa nii Oba ti ilu  Kano, Muhammadu Sanusi; Alayelua Ooni ti ile ife Oba Eniitan Ogunwusi, billionaire ati onisowo pataki, Hajia Bola Shagaya; Senator Ita Giwa; Nike Osinowo; Erelu Dosunmu, Sisi Abah Folawiyo ati be e be e lo.

Tu face ati Darey fi iduunu gboriyin fun Olori naa fun arojinle ati emi imore ti Olori naa fi han sii Olorun.  Eyi ti omu kio ronu lati ranti awon omo alaini. Olori wuraola se ipinu wipe ohun yio rii daju wipe iru concert yi tun waye laipe,  ati wipe ohun tun setan lati fi concert naa lole kaakiri agbaye.

Monday, 20 March 2017

OWO OFIN TI TE AYEDERU OLOPA KAN TI ON FI IPA GBA RI BA LOWO AWON ARA ILU

OWO OFIN TI TE AYEDERU OLOPA KAN TI ON FI IPA GBA RI BA LOWO AWON ARA ILU

Leyin opolopo odun ti Olaiwola Animashaun tin fi eru gba ibukun.  Owo ofin papa mu,  won ni bi iro ba lo logun odun,  ijokan ni otito a telee.

Ogbeni Olaiwola ti oje omo odun merin le logbon yi ti pe ara re ni olopa fun awon aniyan kaakiri,  ti osi tun fi ipa gba owo lowo awon ara ilu,  sugbon owo awon olopa ti baa bayi.  I wadi fihan wipe otin se ise buruku yi tipe.  Ofe lo bere ise re ni ojo ti owo o palaba re se gi,  ni abe afara a tii Ojuelegba,  sugbon ni igba ti ori oko awon olopa,  ni oba fi ese fe.  Sugbon won to pinpin re de Thomas Animashaun Street,  ni Aguda Surulere.

Awon ara adugbo naa fi to akoroyin wa leti wipe gbogbo igba ni arakunrin naa man fi ipa gba owo lowo awon awako ati olokada ni agbegbe surulere,  ojuelegba,  stadium ati awon agbegbe ree.

Agbenuso awon olopa kan ni o so wipe ohun wa lara awon ti o to pin pin arakunrin yi de ile re,  ti won si iri kaadi idanimo ti ijo ipinle eko,  ada ati ero ibani soro o ti awon olopa.  Alukoro fun awon olopa  tii ipinle eko ti so wipe yio fi oju ba ile ejo.

DOKITA BE SOMI LATORI AFARA THIRD MAIN LAND BRIDGE, NI ILU EKO

DOKITA BE SOMI LATORI AFARA THIRD MAIN LAND BRIDGE, NI ILU EKO

Oro di bo o lo yago ni irole ojo isinmi to koja ni igba ti Onisegun Oyinbo Dokita kan dede da Direba re duro to si silekun oko jiipu Nisan to ni namba idako moo LND 476EE to si be somi Osa .Gege bi awon ti Isele ohun se oju won se so , won ni Direba so pe , fonu oga dun ti oga si gbe e ipe yi sugbon leyin ipe n se ni Oga pase pe ki ohun duro ati pe ohun fe wo ikankan , a fi jua ninu Osa !Ah ! E emo ! ni igbe ti gbogbo awon ero ti won fe woko ti Isele yi soju won nke e . Iroyin fi towa leti wipe lati ile ijosin ni arakunrin naa tin bo wa.  Lesekese ni awon Olopa lati Adeniji Adele mu Awako okunrin Dokita yi ati jiipu re lo si Ago won fun iwadi . Amo o , awon Ajo to n ri si isele pajawiri ( LASEMA) ati awon Panapana pelu iranwo awon apeja n wa oku arakunrin naa titi di asiko ti a n ko iroyin yi Jo o .

Thursday, 15 September 2016

MINISTA FUN ASA ATI OKIKI ORILE EDE NAIJIRIYA TI SO PE AWON YIO SE ATUN TO ETO AJOYO TI ILU ABUJA


MINISTA FUN ASA ATI OKIKI ORILE EDE NAIJIRIYA TI SO PE AWON YIO  SE ATUN TO ETO AJOYO TI ILU ABUJA TI AMO SI ABUJA CARNIVAL. KI OLE FI IGA GBAGA PELU AWON TI ILE OKEERE.

Ni ILU ABUJA ni o ti so eleyi di mimo ni ibi ipade gbogbo gboo to waye ni Ilu Abuja.

Minista fun asa ati ogo orile ede naijiriya, Alhaji Lai Mohammed ti fi owo soya wipe ohun setan lati gbe igbese ti omaa mu ki carnival ti Ilu Abuja lee fi egbekegbe pelu awon to oke oku.

Awon oniroyin ti fidi re mule pe carnival ti Odun yio je ki oro aje wa ni orile ede yi tun bo gbooro si. osi ro gbogbo gboo wipe ki won o gbaradi lati se agbateru carnival naa. Carnival naa yio waye ni 19 si 22 osu kokanla Odun yi.

Kunle Afolayan ati Seun akuti f'erin f'erin peeta


Kunle Afolayan ati Seun akuti f'erin f'erin peeta ninu aworan titun yi.  Kunle Afolayan fi idunnu Han lati se alabapade Seun Kuti lairo tele. OSI nii one idunnu fu ohun lati tun pade re, lehin opo odun sehin. Eyi lomu awon mejeji Jo ya aworan papo ti won si gbe si ori ero aye lujara ti an peni "Instagram"

Olu Jacob ati Joke silver Fa ako yo ninu foto tuntun.

Olu Jacob ati Joke silver Fa ako yo ninu foto tuntun.

Awon agba osere ori itage ni Alagba Olu Jacob ati Joke silver tun yo bi Ojo, ninu foto tuntun ti won ya ni ibi  ifihan fiimu titun ti akole re je aadorun le meta. Ni Ile ijosin ti amp si "Rock Cathedral" lekki.